top of page
Blog: Blog2
Search
olusegundare

Ó Kan Ìwọ Náà


Ó KÀN ÌWỌ NÁÀ

Lati ọwọ


ÒGÚNDÁRE OLÚSẸ́GUN OLÚFẸ́MI

© ÒGÚNDÁRE OLÚSẸ́GUN OLÚFẸ́MI (2015)



Email: segundare111@gmail.com Facebook: Olusegun Ogundare

Twitter: Ogundare Olusegun

Telegram: Olusegun O. Ogundare

Vk.com: Olusegun Ogundare

LinkedIn: Segun Ogundare

Tumblr: olusegundare

Veenner chat: Ogundare Olusegun O.

WhatsApp: +2347037106880

Cellular: +2348026301717

ISBN:

ÀFIYÈSÍ PÀTÀKI: Ẹnikẹni ko gbọdọ se atuntẹ tabi da ohunkohun kọ ninu iwe yi yàtọ̀ fun ilo ara rẹ nikan tabi fun sise iwadi laigba àsẹ lati se bẹ lati ọdọ onkọwe. Òfin yi ko yọ ẹnikẹni silẹ yálà latari sise iwe ọlọrọ-geere yi i lori ìtàgé, lori ẹrọ asọ̀rọ̀mágbésì, lori fíimu, ẹ̀rọ-amohun-maworan tabi intanẹti. Ikilọ pataki ni o, o si ti dòfin.

Ilé Isẹ́ to tẹ iwe yi jade ni:

Ilé Isẹ́ to pin to si nta ni Ile Itawe ADURALAGBA (i.e. ADURALAGBA BOOKSHOP), Ilorin, Kwara-state, Nigeria. +2348038493921.

Facebook: Ogundare Richard

ÌBÀ

Ìbà ni fun Oluwa to njẹ Agbara, sugbọn ti awa eniyan npe ni alagbara. Agbara ni, Alagbara nã ni, sugbọn Òun kúkú l'AGBARA tó nfun gbogbo alagbara lagbara ti wọn nlo. Ìba ni fun Un fún agbara to fi fun mi lati kọ iwe yi jade, lai ba se tirẹ, ẹni àná ni ngo ba ti jẹ́, KÁBÍYÈSÍ O.

ÌDÚPẸ́

Ọpẹ pataki lọwọ awọn obi mi nipa ti ara, Alagba Ogundare Ayọdele ati Ogundare Shola, (ẹnito sun ninu Oluwa ni ọdun 2015) fun ilakaka wọn lori mi lati ri wipe mo dide laiye.

Mo dupẹ lọwọ awọn aburo mi gbogbo: Kẹmi, Pamilerin, Tola, Rotimi, ati Ife. Ọpẹ mi ko lopin fun igbagbọ ti awọn ọmọ mi ninu ẹmi ni ninu mi, awọn bi: Ohiare Julius (ọmọ to fi ọrọ sisọ jọ baba rẹ minutes Ẹmi), Fatoyinbo Taiye, Segun Kayode, Ibiwoye Oluwaferanmi.. Mo dupẹ lọwọ awọn enia wọnyi: Kunle Peleyeju, Ọmọtọsọ Adeyẹmi, Ogunrinde Ariyọ, Iyafin Iyabọ Randle, Ojẹlade Kayode, Adeoye Funsọ, Makinde Adeoye, Jeje Olasunkanmi, Ayọbami Adegunlẹ, Gboyega Ọkẹ, Seyi Ajao, ologbe Peteru Adetimọlẹ, Ogunleye Supọ, Shola Idowu Samuel, Ọpẹyẹmi Fakunle, Awoyọde Adewumi, Fagbemi Shọla, Alongẹ Abiọdun, Oguntade Toyin ati idile wọn gbogbo. Adeyemi Anjorin (Canada), Adeyemo Adeyinka (America), Abiodun Gowan Samuel, Ofakunrin Olugbenga, Ejide Isaac, Oyerinde Ganiyu, Ọmọtọsọ Adéyẹmi, Iya agba Olowoniyan Hannah. Mo dupẹ lọwọ onigbagbọ (CAN) to mbẹ ni Ilẹmẹsọ-Ekiti ati lorilẹ-ede Naijiria, Ijọ Aposteli ti Kristi (C.A.C) Oke-Pisga, Ado-Ekiti; C.A.C. Oke Majẹmu, Ogbomosọ, World Flaming Gospel Church, Ibadan, Imọlẹ Otitọ ati awọn ti aye kuna funmi lati darukọ sihinyi, gbogbo ni mo mọ riri wọn. Jesu yio mu gbogbo wa dele o. Amin.


Ọ̀RỌ̀ ÀSỌSÍWÁJÚ ỌRỌ LÀTẸNU ONKỌWE

Iwe Ihinrere ti Matteu ori kẹtala jẹ iwe to kun fun oniruru owe, ati awọn afijọ ati awọn afiwe lati fi le mu ki oye ijọba Ọlọrun o yé eniyan gbogbo. Jesu sọ awọn ọrọ wọnyi ki a ma ba si ninu okunkun nipa awon ojuse wa ti a nilati se toba jẹ wipe lotitọ ati lododo ni a fẹ pada de ilu ọrun. Awọn owe gbogbo to mbẹ ninu iwe yi na ni a wo ni isisẹ ntẹle lati fi pese ero ati ọkan wa silẹ de ijọba aiyeraiye na….

Iranlọwọ Kristi Jesu ni mo rigba lati se eleyi, mo si nigbagbọ wipe bi iwọ na ba le è niwe yi, iwọ pẹlu yio ri ohun kan tabi meji kọ ninu rẹ, eleyi ti yio ran irin ajo igbagbọ rẹ lọwọ padà silu ọrun; Jesu yio si ran ẹ lọwọ lati se eleyi.

-Olusegun, 2016.


ÀKỌỌ́NÚ Oju Ewe Akọle, Iba, Idupẹ, Akọsọ/Asọsiwaju, Akọọnu/Itọka Ọrọ Lerefe, Ipin Kinni


Ọ̀RỌ̀ LÉRÈFÉ ỌRỌ NIPA IWE

ỌNA WO LO GBA KAN Ọ?

Ẹkọ ti Olusọagutan ati olukọ wa ti bẹrẹ sini kọ wa lati nkan bi osu melokan sẹhin ni ẹkọ yi, ẹkọ na ni wọn fun ni akori gboro, "Ó KÀN IWỌ NA" pẹlu. Olukọ wa nigbato nside ẹkọ yi fun wa lọjọ akọkọ ti a o bẹrẹ ẹkọ yi fi ye wa wipe gẹgẹbi oniruru isẹ ti se wa laiye ọjọun ana ti ọlaju ko i ti de, ti imọ nipa ijinlẹ ko i ti pọ to bayi ati ti ihinrere ko i ti de, awọn baba wa igbanã nse isẹ. Isẹ ti onikaluku wọn nse le yatọ si ara wọn tabi ki awọn miran ma se isẹ kanna bi o ti se ri lode oni. Bi oniruru isẹ ti se wa yi ohun na lo mu ki aiye igbana wa lọkansoso ti onikaluku si mojuto isẹ tirẹ, ẹnikini ko se ilara ẹnikeji, bẹni wọn ko ma jà si olori ati owo ọ̀yà wọn, irufẹ eleyi ti ko si lode oni. Gbogbo wọn ti wa mojuto ipin isẹ wọn wọnni, a wa ri wipe lati mu ki ihinrere o le ye wọn yégéyégé Jesu wa mu ọ̀pọ̀ isẹ́ òójọ́ awọn eniyan wọnyi lati fi kọ wọn lẹkọ ijọba Ọlọrun. Eleyi ni wipe o fi ohun to ye wọn, Jesu fi ohun ti wọn mọ nipa rẹ, Jesu fi ohun ti wọn rí arídaju rẹ lati fi salaye ijọba Ọlọrun fun wọn, ki awọn eniyan igbana bà á le mọ wipe ọrọ nipa ijọba Ọlọrun yi kò yọ ẹnikẹni silẹ rara ati rara.

Ohun ti olukọ wa mu ki a mọ ni eleyi to si mu wa si aiye ode oni pẹlu lati fi salaye fun awa na wipe eyikeyi isẹ ti a le ma se, irufẹ ipokipo to wù ki a ma salai wà, ọrọ ijọba Ọrun yi kàn awa na pẹlu.

Ọpọ ninu awọn nkan to wa ninu iwe yi ni aye ko si fun olukọ wa lati sọ fun wa nigbati wọn fi nkọ wa lẹkọ na, sugbọn wọn ti wa kó gbogbo rẹ jọ sinu iwe yi: Ó KÀN Ọ́, yio dara bi iwọ na ba le è ni iwe na nitoripe wa ri oniruru ohun kọ́ ninu iwe na eleyi ti yio ran igbesi aiye igbagbọ rẹ lọwọ.

Mo ngba wa niyanju lati ni iwe yi ninu ile wa, ki a si tun rà a fun awọn ara ati awọn ọrẹ wa nipa sise eleyi a nmu ki ihinrere Kristi o tẹsiwaju na ni.... Bi a tile ra asọ torẹ, bi a ti le ra ẹbun fun awọn to nse ọjọ ibi ati oniruru ayẹyẹ ati ináwó gbogbo, ẹ jẹ ki a ra iwe yi na gẹgẹbi ẹbun fun awọn ololufẹ wa gbogbo. Jesu yio ran wa lọwọ lati se eleyi.

Lakotan mo gbadura wipe ki Ọlọrun ba wa ran olukọ wa lọwọ, ki o si tun fun ni ọgbọn, imọ ati oye lati ma salaye ọrọ ijinle bibeli fun wa.... Lopin gbogbo rẹ, ki Ọlọrun mu wa de ijọba Ọlọrun na nitoripe olori ayọ ati ilepa wa ni lati pada de ijọba Ọlọrun; nitori JESU KRISTI Oluwa wa. Amin

-Olusọagutan Alongẹ Abiọdun,

Ijọ Aposteli ti Kristi (C.A.C.) Oke Pisga,

Ado-Ekiti, Ipinlẹ Ekiti.

+2347034922038




O lè ka ìwé yi lẹkunrẹrẹ lati ipasẹ link tó wà nísàlẹ̀ yi...

6 views0 comments

Recent Posts

See All

HIS PLEA

Comments


bottom of page